Barack Obama
Barack Obama | |
---|---|
44th President of the United States | |
In office January 20, 2009 – January 20, 2017 | |
Vice President | Joe Biden |
Asíwájú | George W. Bush |
Arọ́pò | Donald Trump |
United States Senator from Illinois | |
In office January 3, 2005 – November 16, 2008 | |
Asíwájú | Peter Fitzgerald |
Arọ́pò | Roland Burris |
Member of the Illinois Senate from the 13th district | |
In office January 8, 1997 – November 4, 2004 | |
Asíwájú | Alice Palmer |
Arọ́pò | Kwame Raoul |
Àwọn àlàyé onítòhún | |
Ọjọ́ìbí | Barack Hussein Obama II Oṣù Kẹjọ 4, 1961 Honolulu, Hawaii, U.S. |
Ẹgbẹ́ olóṣèlú | Democratic |
(Àwọn) olólùfẹ́ | Michelle Robinson (m. 1992) |
Àwọn ọmọ |
|
Àwọn òbí | |
Relatives | See Family of Barack Obama |
Education |
|
Awards | Nobel Peace Prize (2009) Profile in Courage Award (2017) |
Signature | |
Website |
Barack Hussein Obama Jr. (ojóìbí 4 August, 1961) jẹ́ òlòsèlú àti Ààre Orélè-èdè ilè Amerika tele.[1] A bí Barack Obama ní ọjó ìkérin, oṣù èkéjọ, odún 1961. Ó jé òloṣèlú orílè èdè Améríkà, ọmọ ilé ìgbìmó aṣòfin láti ìpínlè Illinois, ọmọ ẹgbé òṣèlú Democrat. Barack Obama jé òkan nínú àwọn òṣèlú méjì tí wón figa gbága láti je Àrẹ ilè Amerika. Ẹni èkejì ni John Mccain. Ni ọjọ́ kerin osú kokànlá odún 2008 Obama wolé ìbò fún ipò Ààre ilè Amẹ́ríkà. Obama gorí oyè ní ogún jó osù kinni odún 2009. Barack Obama jé ènìyàn dúdú àkọ́kọ́ tí òkan nínú àwọn egbé òṣèlú nlá ti ilè Amerika fún ní ànfàní láti kóra nínú eré ìje àti di Ààrẹ ilè Amerika láti ẹgbẹ́ òṣèlú Demokratiki.
Igbesiaye[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Wón bí Barack Obama ní ìlú Honolulu, ìpínlè Hawaii ní ọdun 1961. Àwòn òbí ré rí ara won ní ìgbà tí wón nka ìwé ní ilé èkó Unifásítì Hawaii ní ìlu Manoa. Bàba rè wá láti orílè èdè Kenya.[2][3] Barack Hussein Obama- àgbà, lọ ka ìwé nípa òrò ajé ní ilè Amerika. Ìya rè, ènìyàn funfun, ọmọ ilè Améríkà, Stanley Ann Dunham, jé ọmọ ilé èkó Unifásítì láti ìlu Wichitta, ìpínlè Kansas. Àwọn òbí ìya rè lòdì sí àjọṣe àwọn méjèjì, ṣùgbón wón fé ara wọn ní odún 1960.[4] Ọdún méjì léhìn tí wón bí Obama, bàbá rè lọ si Howard fún ìtèsíwájú èkọ rè, ṣùgbón kò mú ẹbí rè lọ nítorí àìsí owó. Ní àìpé ọjó wón yapa. Ní ìgbà èkó rè ní Howard, Obama- àgbà fé Ruth Nidesand, ẹni tí ó bá padà sí orílè èdè Kenya léhìn ìparí èkò rè. Ruth Nidesand jé ìyàwó rè ẹ̀kẹ́ta, wón sì ní ọmọ méjì. Ní orílè èdè Kenya, Obama- àgbà bèrè iṣé ní ilé iṣé tí ó nwa epo ròbì, léhìn èyí, ó ṣiṣé fún ìjọba, gégébí olóòtú ètò ọrò ajé. Ó fi ojú kan ọmọ rè, Obama, ní ìgbàkan péré- ní ìgbà tí oní tòhún pé ọmọ ọdún méwàá. Obama- àgbà fi arapa nínú àgbákò ọkò nípa èyí tí ó sọ ẹsè méjèjì nù. Ní ìgbà tí ó pé ọmọ ọdún mérin-dí-láàdóta, ní ọdún 1982, ó sọ èmí rè nù nínú àgbákò ọkò.
Léhìn ìyapa pèlu bàba Obama, ìya rè fé Lolo Soetoro, ọmọ ilé èkó gíga unifasiti láti orílè èdè Indonesia. Ní ọdún 1967 ó sì bá Lolo Soetoro lọ sí Indonesia. Barack Obama ní ọbàkàn, obìnrin, ọmọ Lolo àti Stanley Ann. Stanley Ann Dunham pèhìndà ní ọdún 1995.
Ìwé tó kọ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
- Obama, Barack. Dreams from My Father: A Story of Race and Inheritance, Times Books, 1995. Reprint edition, 2004; ISBN 1-4000-8277-3
- Obama, Barack. The Audacity of Hope: Thoughts on Reclaiming the American Dream, Crown, 2006. ISBN 0-307-23769-9.
Àwọn ibùdó lori Interneti[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
- ↑ "President Barack Obama". Washington, D.C.: The White House. 2008. Retrieved December 12, 2008.
- ↑ Maraniss, David (August 24, 2008). "Though Obama had to leave to find himself, it is Hawaii that made his rise possible". The Washington Post: p. A22. http://www.washingtonpost.com/wp-dyn/content/article/2008/08/23/AR2008082301620.html. Retrieved October 28, 2008.
- ↑ Nakaso, Dan (December 22, 2008). "Twin sisters, Obama on parallel paths for years". The Honolulu Advertiser: p. B1. http://the.honoluluadvertiser.com/article/2008/Dec/22/ln/hawaii812220320.html. Retrieved January 22, 2011.
- ↑ Rudin, Ken (December 23, 2009). "Today's Junkie segment on TOTN: a political review Of 2009". Talk of the Nation (Political Junkie blog). NPR. Retrieved April 18, 2010.
We began with the historic inauguration on January 20 – yes, the first president ever born in Hawaii
Wikimedia Commons ní àwọn amóunmáwòrán bíbátan mọ́: Barack Obama |