BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
NÍ YÀJÓYÀJÓ Ètò ìdìbò gómìnà ní Anambra ti gbérasọ
BBC Yorùbá ti wà níkàlẹ̀ láti mú ìròyìn wá fún yín nípa ìdìbò gómìnà ní Anambra.
Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí
Gbọ́, Ìṣẹ́jú kan BBC, Duration 1,01
Àkójọpọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ jákèjádò àgbáyé láàárín ìṣẹ́jú kan lórí BBC.
Màá ṣèrànwọ́ láti dojú ìjà kọ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ nílẹ̀ Niger tó pa èèyàn 69 - Buhari
Buhari ni asiko ti wa to bayii lati wa egbo dẹkun fawọn agbesunmọmi to n ṣakoba fun ọrọ aje awọn orilẹede lapa iwọ oorun Afirika
Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí àti dúkìá sọnù sínú ìjàmbá iná Kẹrosínìì l‘Abuja
Nibayii, awọn ọlọpaa, awọn osisẹ panapana atawọn osisẹ adoola ẹmi nibi isẹlẹ pajawiri lo ti de sibi isẹlẹ naa.
Fídíò, Wo àwọn ọmọ tí àìsí èròjà protein ń dà láàmú, tí òbí wọn rò pé iṣẹ́ ayé ni, Duration 7,54
BBC se iwadi ohun to n mu kawọn ọmọde maa se aisan lọpọ igba ati ewu to wa ninu rẹ.
Ìròyìn àpapọ̀ Nàíjíríà
Ìkúnlẹ̀ Abiyamọ oo! Ìyá ju ọmọ rẹ̀ méjì sí Kànga
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ni àwọn yóò ṣe àyẹ̀wò fún bọya lóòtọ́ ni o ni ààrùn ọpọlọ.
Ìdìbò gómìnà Anambra gbérasọ, ìíú dá wáí-wáí, aráàlú ń sá kíjo kíjo
Awọn eeyan kan sa kuro nipinlẹ Anambra lati sa asala fun ẹmi wọn nitori wọn ko mọ ohun to le ṣẹlẹ lasiko eto idibo.
"Ó dùn mí pé èmi ló bí Abubakar Shekau tó dá ayé lóró"
Falmata Abubakar ni ohun kan to pa awọn mejeeji pọ ni pe oun lo bi i lọmọ, o tan.
Ọ́dọ́kùnrin 18 láti òkè ọya pẹ̀lú ohun ìjà olóró dojú ìjà kọ Àmọ̀tẹ́kùn l'Ondo
Ọga ikọ Amọtẹkun Ondo sọ fun BBC pe loru Ọjọbọ lawọn ikọ Amọtẹkun ṣalabapade awọn ọdọ yii nigba ti wọn fẹ wọ Ondo.
Kí ló so Yemi Osinbajo pọ̀ mọ́ ilé alájà púpọ̀ tó dà wó ní Eko?
Oniruru iroyin lo gba ori ayelujara kan nipa Yemi Osinbajo ati ile alaja mọkanlelogun to wo ni Eko, iwadii ree.
Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha
Ikọ olupẹjọ mu ẹlẹri kan wà ṣiwaju adájọ lati sọ ohun ti oju rẹ tó nípa igbẹjọ náà lónìí.
Kókó méjìlá nípa ìgbé ayé Femi Osibona
Ọjọbọ, ọjọ Krin osu Kọkanla ọdun 2021 ni wọn kede pe Femi Osibona to ni ile alaja mọkanlelogun to da wo ni Ikoyi ti jade laye.
Mo kúrò ni ṣọ́ọ́ṣì kan nígbà tí Pásítọ̀ ń bú Buhari - Femi Adesina
Adesina ni ọ̀pọ̀ àwọn oníwààsú ti sọ ilé ìjọsin di ibi ti wọ́n ti n polongo ìrunú àti ibínú sí awọn alásẹ, ti wọn si n wàásù ìròyìn òfégè lọ́sẹ̀-ọ̀sẹ̀.
Gómínà díbọn lọ ilé ìwòsàn, òṣìṣẹ ìlera tó gba rìbá N10,000 wọ gàù
Gomina Zulum wa pasẹ fun ajọ to wa feto ilera alabọde nipinlẹ Borno lati tu isu de isalẹ koko nipa awọn osisẹ ile iwosan naa lati yọ kanda inu irẹsi.
IPOB fagilé òfin kónílé-ó-gbélé ọlọ́sẹ̀ kan ṣáájú ìbò gómìnà Anambra
Akọwe iroyin ẹgbẹ IPOB, Emma Powerful ni awọn wọgile ofin konle o gbele naa lẹyin tawọn eekan ilu at'awọn lọba lọba nilẹ Igbo parọwa s'awọ.
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
"Ọ̀rẹ́kùnrin tá a fẹ́ra fún ọdún marùn ún fi ọta ìbọn yí kádàrá mi padà"
Kaakiri loju opo ayelujara lawọn eeyan ti n ṣe kayeefi lori iṣẹlẹ ibọn to fẹ gbẹmi Purity.
Buhari, dẹ̀yìn lẹ́yìn Sunday Igboho, Akintoye àti Kanu- Ẹgbẹ́ ọmọ Yorùbá kìlọ̀
Ẹgbẹ agbarijọpọ ọmọ Yoruba to n pe fun iyapa Naijiria ni ijọba Buhari gbọdọ mọ pe igbesẹ lati pa Igboho, Kanu ati Ọjọgbọn Akintoye kọ ni ọna lati dẹkun ipe fun iyapa.
Ǹ jẹ́ o mọ̀ pé Femi Osibona ta bàtà àti aṣọ kóòtù rí, kó tó di akọ́létà?
Femi Osibona ni akọleta ọmọ ilẹ Afirika akọkọ to kọ ile alaja meje lorilẹ ede UK, to si tun ni ẹka si orilẹede South Africa.
Ẹ̀kùn Àríwá pahùndà, ó fẹ́ sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yà míì láti yan ààrẹ
Ẹgbẹ NEF sọ pe anfaani pupọ ni yoo jẹ fun awọn ọmọ Naijiria, ti awọn ẹgbẹ́ oṣelu miran ba wà, yatọ si PDP ati APC.
"Amẹ́ríkà ni Wale Bob-Oseni ń lọ, ìpè fóònù tó gbà, ló gbe lọ síbi ilé tó dà wó"
Ilẹ Amẹrika ni Wale Bob-Oseni n lọ, ko to gba ipe lati yọju sí ilé náà, ti ko si pada sile rẹ mọ tàbí lọ sí Amerika to ti pinnu rẹ lati lọ bákan náà.
"Pásítọ̀ onímọ̀ ẹ̀rọ kan àti lébìrà 18 tó kó wá láti Ibafo sì wà lábẹ́ ilé Ikoyi "
Nibayii, wọn mọ̀lẹ́bí olóògbé ti yarí pé kí ìjọba gbé òkú ẹni wọn fún àwọn nibi ile to da wo ni Ikoyi.
Ọwọ́ tẹ oníṣègùn níbi tó ti ń sin ọmọ tuntun láàyè pẹ̀lú ọfọ̀ àti àyájọ́
Ileẹṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ni awọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, amọ wọn n reti alaye lẹkunrẹrẹ lati ọọfisi ẹka ti Ahoada.
Wo àkọsílẹ̀ nípa ìtan ayé àwọn oludìbò gómìnà Anambra
BBC se akojọpọ ranpẹ nipa itan igbe aye awọn oludibo nipinlẹ́ Anambra.
Bí o ṣe le mọ ìbùdó ìdìbò rẹ̀ ní Anambra
BBC se alaye nipa bi awọn oludibo se le mọ ibudo idibo wọn fun ibo gomina ipinlẹ Anambra.
Tinubu, àtúntò Nàíjíríà ni ko wá ná, ko tó du ipò ààrẹ - Pa Adebanjo
Adarí ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re ni Nàìjíríà, olóyè Ayo Adebanjo ní bí ó jẹ́ ọmọ òun ló fẹ́ dupò ààrẹ, òun kò ni gbárúkù tí, tí kò bá sí àtúntò Nàìjíríà.
Liverpool faṣọ iyì ya mọ́ Man U lára, ó wọ Ole àti Ronaldo láṣọ ẹ̀tẹ́
Ẹlẹsẹ ayo n ni, Mohammed Salah lo gbayo mẹta ọtẹtọ wọlé fun Liverpool ninu ere bọọlu ọhún.
Tottenham forí kó 3-0, ìpadàbọ̀ abìjà ni Man Utd fi ṣe fún wọn
Ẹwẹ, Arsenal naa pegede ninu ifẹsẹwọnsẹ ti wọn gba pẹlu Leicester ti wọn sun soke si ipo kẹfa lori afara Premier League.
Fídíò, "Mo gba àmì ẹ́yẹ wúrà fún Nàíjíríà ní Tokyo 2020 àmọ́ ìgbé ayé mi ń burú si ni", Duration 4,28
BBC Yoruba ba akanda elere idaraya, Latifat Tijani sọrọ lori ohun to n la kọja lẹyin to gba ami ẹyẹ fadaka fun Naijiria lọdun 2016 ati Wura lọdun 2020 láì ri iranwọ ijọba.
Àìle jà ni ìta baba mi kò dé ibí, Central African Republic na Naijiria mọ́lé
Awọn agbabọọlu orilẹ-ede Central Africa Republic fiyajẹ Super Eagles ti Naijiria.
Móríwú
Fídíò, Oríadé ni mí àmọ́ mo sì ń tẹ dùùrù ní ṣọ́ọ́ṣì láti yin Ọlọ́run - Ọba Mesach Oyediran, Duration 4,04
Ọba Mesach Oyediran ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba ni ọdun mejidinlogbọn ree ti oun ti n tẹ duuru, ti oun si setan lati tẹsiwaju.
Fídíò, Abiyamọ ayé, ẹ bá mi wá ọmọ mi tí agbófinró gbé, alájọṣepọ̀ pẹ̀lú Sunday Igboho ni - Ìya Arifanlajogun, Duration 5,02
Yeye Olomitutu Fasooto ke gbajare tọ BBC Yoruba wa pe oun n wa ọmọ oun tii se alajọsepọ Sunday Igboho, ti awn ko si mọ ibi to wa lẹyin osu mẹta.
Fídíò, Kàyèéfì! Mo ní àrùn jẹjẹrẹ tẹ́lẹ̀ àmọ mo bí ìbejì lẹ́yìn tí nǹkan oṣù ti dúró - Olorì Olugbon, Duration 5,13
BBC Yoruba ba Olugbon tile Igbon ati Olori rẹ sọrọ nipa ọna ara ti Ọba Oke fi ibeji ta wọn lọrẹ lẹyin ti awọn mejeeji ti dagba.
Fídíò, Mo ti ránṣẹ́ sí ìyá mi pé kò fi aṣọ funfun sin mí lọ́jọ́ tí DSS ká mi mọ́ ilé Sunday Igboho - Omiyale, Duration 10,59
Onaolapo Ademola Omiyale, tii se ọ̀kan lara awọ̀n eeyan ti DSS ko nile Sunday Igboho ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ nipa bi isẹlẹ naa se waye ati ohun ti oju rẹ ri ni ahamọ DSS.
Fídíò, Màá ṣe àtúnṣe níbi tó bá kù sí pẹ̀lú igun PDP tó ń bínú l‘Oyo - Seyi Makinde, Duration 6,11
Gomina Seyi Makinde, ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, tun sọ nipa aayan rẹ lori eto ẹkọ, atunse oju popo yika ipinlẹ Oyo ati ipese eto ilera to yanranti fawọn eeyan ipinlẹ Oyo.
Fídíò, Wo ọ̀nà to fi le lo ‘Social Media’ láti mú okoòwò rẹ dàgbà - Kiki Osinbajo, Duration 6,13
Kiki Osinbajo, tii se ọmọ igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ba BBC Yoruba sọrọ nipa bo se bẹrẹ okoowo lai naani pe amofin ni oun.
Fídíò, Kò yẹ kí àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run máa kiri ilé ìjọba, kí ni wọ́n ń wá? - Timi Osukoya, Duration 5,29
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Osukoya ni ẹmi mimọ lo maa n dari awọn olorin ẹmi bii toun ni ọpọ ọdun sẹyin, nipa orin ti awọn yoo gbe jade.
Fídíò, A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa - Ooni Ife, Duration 8,33
Ọba Adeyeye Ogunwusi ni ọpọ awọn eeyan to n ti Igboho lẹyin lo wa loke okun, ti ipo ti orilẹede Naijiria si wa n ka wọn lara nitori ọpọ wọn lo fẹ wa sile pada.
Fídíò, Ogogo wá sí illé-ẹ̀kọ́ wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi, Duration 4,19
Akinwumi Farooq di gbajúmọ̀ lórí ayélujára lẹ́yiìn tí arákùnrin kan tó jẹ́ àlejò ńlá nílé ẹ̀kọ́ rẹ̀ gbée sórí ayélujára.
Fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi', Duration 9,31
Oluseyi ba BBC Yoruba sọ nipa bo ṣe n ko imọ iṣegun mejeeji yii pọ. Bo ba ṣee ni ti oyinbo ti ko jẹ, a si ti ẹsẹ ile bọ ọ boya ifa yoo jẹ.
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ọkùnrin kan wọ gàù torí ó fi sísọ́ọ̀sì gún aya rẹ̀ pa
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Lanre Bankole ti paṣẹ pe ki wọn gbe ẹjọ naa lọ si ẹka iwadii ẹsun ipaniyan fun iwadii to peye.
Ìjọba Ethiopia figbe ta pe ogun ń bọ, ó kéde ìlú kò fara rọ
Nibayi naa, ijọba ilẹ Amẹrika ti wa n ke si awọn ọmọ orilẹede rẹ lati fi orilẹede Ethiopia silẹ ni kiakia.
Àsìta ìbọn bá àkẹ́kọ̀ọ́ Poly Ibadan, bí ọ̀rọ̀ ṣe wáyé rèé
Awọn alasẹ ile ẹkọ Gbogbonse Poly Ibadan ni iwadii n lọ lọwọ lori isẹlẹ naa.
Ọwọ́ Amotekun tẹ ọ̀dọ́ 18 tó rìn gbéregbère wọ Akure láti òkè ọya
Wọn ti fa wọn le awọn adari ẹgbẹ Miyetti Allah lọwọ.
Fídíò, Irú omi àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún Sunday Igboho, a ó mọ̀ọ́, à ń fura sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ látìmọ́lé Cotonou, Duration 9,16
Alhaji Ajikobi jẹ ko di mimọ pe nibi ti ọrọ de duro bayii, awọn lọba lọba Yoruba gbudọ dide lati kopa ninu wiwa itusilẹ Oloye Sunday Igboho.
Ó di dandan kí a wa iṣu dé ìṣàlẹ̀ kòkò l'órí ọ̀rọ̀ ilé tí ó wó ní Ikoyi-Tinubu
" Ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tó n wá oúnjẹ òòjọ́ wọn láti tọ́jú ẹbí wọn lo wà níbẹ̀, ṣe ó wá yẹ ki wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọ́n lẹ́nu iṣẹ́?
Ọ̀gá báńkì rẹ́wọ̀n he torí ó fi N219m owó oníbàárà kọ́ ilé, ra ilẹ̀
Adajọ pàṣẹ pe ki wọn lọ tá gbogbo dukia ti osisẹ banki tẹlẹ naa fi owo to ko jẹ ra, ki wọn sì da owo ti wọn ba ri níbẹ pada fun banki olokowo kekeke.
Àwọn adarí iléẹ̀kọ́ wọ gàù fún gbígba owò lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà àìtọ́
Awọn ileẹkọ ti wọn fẹsun kan naa ni UBE Ita Ayisa, UBE Olulande, United Secondary School, Taiwo Isale ati bẹẹ bẹẹ lọ in ilu Ilorin.
Èèyàn ogún ló ti sọ ẹ̀mí nù nínú ilé alájà 21 tó wó ni Ikoyi - NEMA
Alábojútó iwọ-òòrùn guusú fún NEMA Ibrahim Fariloye sọ lọjọ́ Iṣegun pe okú ènìyàn ogún ni wọ́n ti kó jáde, tó fi mọ ti amúgbálẹ́gbẹ́ Femi Osibona to ni ilé náà, ti wọ́n sì ti wú okú wọ́n.
Mo fẹ́ dákú níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún mi - Salawa Abeni
Salawa Abeni wa sisọ loju rẹ pe oun maa kọrin lọ lai fi ẹyin ti rara ni.
Fídíò, Òṣì pọ̀ nínú PDP ni Makinde fi ń ra ọkọ̀ àlòkù fọ́mọ́ ẹgbẹ́, tí yóò tún gbe sórí ayélujára - Olopoeyan, Duration 8,40
Amọ akọwe ipolongo fun PDP Oyo, akeem Olatunji ti fesi pada pe aini suuru ki ere ijọba de ọdọ igun to n binu, lo fa ti wọn se n fapa janu.
"Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin Iree Poly pọ ẹ̀jẹ̀ àti itọ́ kó tó kú lẹ́yìn tó dé láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀"
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
A gbọ́ ohùn bí àwọn ènìyàn tó há sí abẹ́ ìlé alájà 21 ṣe ń kérọrà fún ìrànwọ́ – NEMA
Titi di asiko yiii, ko tii si ẹni to le sọ pato nkan to mu ki ile alaja mọkanlelogun naa sadede wo lulẹ.
Ẹ bá mi bẹ ọkọ mi Aláàfin kó gbà mí padà, mo ti ṣe àṣìṣe - Olorì Damilola
Olori Damilola Adeyemi lo ko kuro ni aarin Oyo bii osu marun sẹyin, ni osu April, lori awijare pe Ọba :Lamidi Adeyemi ko tọju oun.
Gómìnà díbọ́n bíi aláìsàn lọ ṣèwádí aṣemáṣe àwọn òṣìṣẹ́ iléèwòsàn, ọ̀rọ̀ kọ sísọ
Eredi igbesẹ gomina naa ni lati tu aṣiri ihuwasi aibikita awọn dokita ati nọọsi ileewosan si iṣẹ ti wọn n gba owo oṣu fun.
Kí ló mú ọkùnrin kan fi ejò Sèbé olóró pa aya rẹ̀ lójú oorun?
Rira tabi tita ejo lodi sofin India tori naa ọna ẹburu ni Suraj fi ra ejo naa lọdọ arakunrin kan to maa n mu ejo laaye, Suresh Kumar nipinlẹ Kerala.
Wòlíì kan fún òṣèré tíátà ní miliọnu mẹ́fà náírà láti fi tọ́jú àìsàn rẹ̀
Ani Chukwuemeka ninu fidio kan to gbe sori ayelujara sọ pe oju oun ti fẹ ẹ fọ́ nitori kokoro 'cataract' to ti wọ inu oju kan.
Akọ̀ròyìn tó fi fọ́nrán ohùn Igboho síta ti wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Cotonou
Ọjọbọ ni awọn ọlọpaa lorilẹede Benin gbe Adekunle Aremu yọju sile ẹjọ lori ẹsun pe o gba ohun Sunday Igboho silẹ, to si fọn sita fara ilu.
Ẹ wo alágbe méje tó lówó jùlọ ní àgbáyé
Akojọpọ awọn alagbe ti wọn lowo bi ṣẹkẹrẹ lagbaye amọ ti wọn ko dẹkun titọrọ owo ree.
Wo ọ̀nà tí obìnrin tó ti ní ìbálòpọ̀ tẹ́lẹ̀, ṣe le sọ ara rẹ̀ di ‘Virgin' lẹ́ẹ̀kejì
Àṣà adayeba nipa ibale lo n mú kí àwọn ọmọge dá ọgbọ́n sí ọ̀rọ̀ ìbálé wọn.
Àkànṣe ìròyìn nípa àrùn Coronavirus
Kàyééfì! Ẹ wó ìyàwó tó ṣán ọkọ rẹ̀ mọ́lẹ̀ tó sí fí àdá bẹ orí rẹ̀!
Iroyin abẹle gbe e pe ede aiyede lo waye laarin awọn tọkọ-taya mejeeji, eleyii to mu ki ọkọ fi ile si ilẹ to si gba oko nkan ọgbin lọ.
Wo ewu tó wà nínú fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ
Dokita Olanike Olutekunbi sọ pe akoko itọju okun to so olubi pọ mọ iya ọmọ bẹrẹ lati igba ti wọn ṣẹṣẹ bi ọmọ naa.
Ṣé o mọ̀ pé o leè kó Covid pẹ̀lú ọmọ ìka ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ láì mọ̀?
Ẹgbẹ awọn dokita onimọ nipa awọ ara nilẹ Britain ni akọsilẹ oniruuru aisan ara to lee ni ṣe pẹlu Covid.
Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
Eniyan nilo ounjẹ lati lee dagba ki o si wa laye.
Ẹ̀dà Delta Variant COVID-19 ń gbèrú síi ní Nàìjíríà, ìjọba àpapọ̀ ra abẹ́rẹ́ àjẹsára 176,000
Nnkan bii ọgọsan ẹgbẹrun eeyan lo ti ko arun naa, ti ẹgbẹrun meji ati igba o din marun un eeyan si ti ti ara rẹ ku.
Ènìyàn 747 míràn ló tún ṣẹ̀ṣẹ̀ lùgbàdì aàrùn Covid-19 ní Nàìjíria
Iye eeyan to n lugbadi arun Coronavirus ti n lọ soke si pẹlu ẹda Delta Variant to wọ Naijiria.
Ìjọba Amẹ́ríkà ti kó abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 mílíọ̀nù mẹ́rin fún Nàìjíríà
Yatọ si abẹrẹ ajẹsara Moderna to kan Naijiria yi, awọn orileede Afrika mii yoo gba miliọnu mẹẹdọgbọn abẹrẹ yi lati ọdọ ijọba aarẹ Joe Biden.
COVID-19 variant tó wà ní Nàìjíríà tún yàtọ̀ sí ti UK - NCDC
Ajọ to n gbogun ti aisan ni Naijiria ni awọn ti ri ọ̀wọ́ keji Covid-19
Ẹ kó àwọn ọmọ ọdún 12 títí dé 15 wá fún abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
Nilẹ Amẹrika ati Canada, wọn ti fi aṣẹ si ki awọn ọdọ langba gba abẹrẹ naa.
Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òògùn ìbílẹ̀ Coronavirus tí Ooni filọ́lẹ̀? Ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ní Covid-19 ló ti gbádùn
Ooni sọ pe ajọ WHO gan an fidi rẹ mulẹ pe orilẹede Naijiria ni awọn egbo to wulo fun ṣiṣe abẹrẹ fun wiwo ọpọlọlọpọ arun.